Nehemiah 4:22 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Mo tún sọ fún àwọn eniyan náà pé, “Kí olukuluku ati iranṣẹ rẹ̀ sùn ní Jerusalẹmu, kí wọ́n lè máa ṣọ́ ìlú lálẹ́, kí wọ́n sì máa ṣiṣẹ́ ní ojú ọ̀sán.”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Li àkoko kanna pẹlu ni mo sọ fun awọn enia pe, Jẹ ki olukuluku pẹlu ọmọkunrin rẹ̀ ki o sùn ni Jerusalemu, ki nwọn le jẹ ẹṣọ fun wa li oru, ki nwọn si le ṣe iṣẹ li ọsan.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ní ìgbà náà mo tún sọ fún àwọn ènìyàn pé, “Jẹ́ kí olúkúlùkù ènìyàn àti olùrànlọ́wọ́ rẹ̀ dúró ní Jérúsálẹ́mù ní òru, nítorí kí wọn le jẹ́ ẹ̀ṣọ́ fún wa ní òru, kí wọn sì le ṣe iṣẹ́ ní ọ̀sán.”