Nehemiah 4:7 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Ṣugbọn nígbà tí Sanbalati ati Tobaya ati àwọn ará Arabu, ati àwọn ará Amoni, ati àwọn ará Aṣidodu, gbọ́ pé a ti ń ṣe àtúnṣe àwọn odi Jerusalẹmu ati pé a ti ń dí àwọn ihò ibẹ̀, inú bí wọn gidigidi.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
O si ṣe, nigbati Sanballati, ati Tobiah, ati awọn ara Arabia, ati awọn ara Ammoni, ati awọn ara Aṣdodi gbọ́ pe, a mọ odi Jerusalemu de oke, ati pe a bẹ̀rẹ si tun ibi ti o ya ṣe, inu wọn ru gidigidi.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ṣùgbọ́n nígbà tí Ṣáńbálátì, Tóbíyà, àwọn ará Árábù, ará Ámónì, àti àwọn ènìyàn Áṣídódì gbọ́ pé àtúnṣe odi Jérúsálẹ́mù ti ga dé òkè àti pé a ti mọ àwọn ibi tí ó yá dí, inú bí wọn gidigidi.