Nehemiah 5:10 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Pàápàá tí ó jẹ́ pé èmi ati àwọn arakunrin mi ati àwọn iranṣẹ mi ni à ń yá wọn ní owó ati oúnjẹ. Ẹ má gba èlé lọ́wọ́ wọn mọ́, ẹ sì jẹ́ kí á pa gbèsè wọn rẹ́.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Emi pẹlu, ati awọn arakunrin mi, ati awọn ọmọkunrin mi, nyá wọn ni owó ati ọkà, ẹ jẹ ki a pa èlé gbígbà yí tì.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Èmi àti àwọn arákùnrin mi àti àwọn ènìyàn mi, pẹ̀lú ń yá àwọn ènìyàn lówó àti oúnjẹ (ọkà). Ṣùgbọ́n ẹ jẹ́ kí a dáwọ́ owó èlé gbígbà yìí dúró!