Nehemiah 5:11 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Ẹ dá ilẹ̀ oko wọn pada fún wọn lónìí, ati ọgbà àjàrà wọn, ati ọgbà igi olifi wọn, ati ilé wọn, ati ìdá kan ninu ọgọrun-un owó èlé tí ẹ gbà, ati ọkà, waini, ati òróró tí ẹ ti gbà lọ́wọ́ wọn.”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Mo bẹ̀ nyin, ẹ fi oko wọn, ọgbà-ajarà wọn, ọgbà-olifi wọn, ati ile wọn, ida-ọgọrun owo na pẹlu, ati ti ọkà, ọti-waini, ati ororo wọn, ti ẹ fi agbara gbà, fun wọn padà loni yi.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ẹ fún wọn ní oko wọn, ọgbà àjàrà wọn, ọgbà ólífì wọn àti ilée wọn pẹ̀lú owó èlé tí ẹ ti gbà lọ́wọ́ọ wọn ìdá ọgọ́rùn-ún owó, oúnjẹ (ọkà), wáìnì túntún àti òróró tí ẹ ti gbà lọ́wọ́ọ wọn padà kíákíá.”