Nehemiah 5:12 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Wọ́n sì dáhùn pé, “A óo dá gbogbo rẹ̀ pada, a kò sì ní gba nǹkankan lọ́wọ́ wọn mọ́. A óo ṣe bí o ti wí.” Mo bá pe àwọn alufaa, mo sì mú kí wọ́n jẹ́jẹ̀ẹ́ láti ṣe ohun tí wọ́n ṣèlérí pé àwọn yóo ṣe.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nwọn si wipe, Awa o fi fun wọn pada, awa kì yio si bere nkankan lọwọ wọn; bẹ̃li awa o ṣe bi iwọ ti wi. Nigbana ni mo pe awọn alufa, mo si mu wọn bura pe, nwọn o ṣe gẹgẹ bi ileri yi.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Wọ́n wí pé, “Àwa yóò dá a padà.” “Àwa kì yóò sì béèrè ohunkóhun lọ́wọ́ọ wọn mọ́. Àwa yóò ṣe bí o ti wí.” Nígbà náà mo pe àwọn àlùfáà, mo sì mú kí àwọn ọlọ́lá àti àwọn ìjòyè búra láti jẹ́ kí wọ́n ṣe ohun tí wọ́n ti ṣe ìlérí.