Nehemiah 5:13 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Mo gbọn àpò ìgbànú mi, mo ní, “Báyìí ni Ọlọrun yóo gbọn gbogbo ẹni tí kò bá mú ẹ̀jẹ́ yìí ṣẹ kúrò ninu ilé rẹ̀ ati kúrò lẹ́nu iṣẹ́ rẹ̀. Ọlọrun yóo gbọn olúwarẹ̀ dànù lọ́wọ́ òfo.” Gbogbo àwọn tí wọ́n wà ní àpéjọpọ̀ náà sì ṣe “Amin”, wọ́n sì yin OLUWA. Àwọn eniyan náà sì mú ìlérí wọn ṣẹ.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Mo si gbọ̀n apo aṣọ mi, mo si wipe, Bayi ni ki Ọlọrun ki o gbọ̀n olukuluku enia kuro ni ile rẹ̀, ati kuro ninu iṣẹ rẹ̀, ti kò mu ileri yi ṣẹ, ani bayi ni ki a gbọ̀n ọ kuro, ki o si di ofo. Gbogbo ijọ si wipe, Amin! nwọn si fi iyìn fun Oluwa. Awọn enia na si ṣe gẹgẹ bi ileri yi.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Mo sì gbọn ìṣẹ́tí aṣọ mi, mo wí pé, “Báyìí ni kí Ọlọ́run gbọn olúkúlùkù ènìyàn tí kò bá pa ìlérí yìí mọ́ jáde kúrò ní ilẹ̀ ìní i rẹ̀. Bẹ́ẹ̀ ni kí a gbọn irú ẹni bẹ́ẹ̀ jáde kí ó sì ṣófo!” Gbogbo ìjọ ènìyàn sì wí pé “Àmín,” wọ́n sì fi ìyìn fún OLÚWA. Àwọn ènìyàn náà sì ṣe bí wọ́n ti ṣe ìlérí.