Nehemiah 5:14 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Siwaju sí i, láti ìgbà tí a ti yàn mí sí ipò gomina ní ilẹ̀ Juda, láti ogun ọdún tí Atasasesi ti jọba sí ọdún kejilelọgbọn, èmi ati arakunrin mi kò jẹ oúnjẹ tí wọ́n yà sọ́tọ̀ fún wa gẹ́gẹ́ bíi gomina.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Pẹlupẹlu lati akoko ti a ti yàn mi lati jẹ bãlẹ wọn ni ilẹ Juda, lati ogún ọdun titi de ọdun kejilelọgbọn Artasasta ọba, eyinì ni, ọdun mejila, emi ati awọn arakunrin mi kò jẹ onjẹ bãlẹ.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Síwájú sí í, láti ogún ọdún ìjọba Aritaṣéṣéṣì, nígbà tí a ti yàn mí láti jẹ́ baálẹ̀ wọn ní ilẹ̀ Júdà, títí di ọdún kejìlélọ́gbọ̀n ìjọba rẹ̀—ọdún méjìlá, èmi àti àwọn arákùnrin mi kò jẹ oúnjẹ baálẹ̀.