Nehemiah 5:15 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Àwọn gomina yòókù tí wọ́n jẹ ṣiwaju mi a máa ni àwọn eniyan lára, wọn a máa gba oúnjẹ mìíràn ati ọtí waini lọ́wọ́ wọn, yàtọ̀ sí ogoji ìwọ̀n Ṣekeli fadaka tí wọn ń gbà. Àwọn iranṣẹ wọn pàápàá a máa ni àwọn eniyan lára. Ṣugbọn, nítèmi, n kò ṣe bẹ́ẹ̀, nítorí pé mo bẹ̀rù Ọlọrun.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ṣugbọn awọn bãlẹ iṣaju, ti o ti wà, ṣaju mi, di ẹrù wiwo le lori awọn enia, nwọn si ti gbà akara ati ọti-waini, laika ogoji ṣekeli fadaka; pẹlupẹlu awọn ọmọkunrin wọn tilẹ lo agbara lori enia na: ṣugbọn emi kò ṣe bẹ̃ nitori ibẹ̀ru Ọlọrun.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ṣùgbọ́n àwọn baálẹ̀ ìṣáájú—tí ó ti wà ṣáájú mi—gbe àjàgà wúwo lé àwọn ènìyàn lórí yàtọ̀ fún oúnjẹ àti wáìnì wọ́n sì tún gba ogójì ṣékélì fàdákà lọ́wọ́ wọn. Kódà àwọn ìránṣẹ́ wọn tún jẹ gàba lóríi wọn. Ṣùgbọ́n èmi kò ṣe bẹ́ẹ̀ nítorí ìbẹ̀rù Ọlọ́run.