Nehemiah 5:18 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Mààlúù kan ati aguntan mẹfa tí ó dára ni wọ́n ń bá mi pa lojumọ, wọn a tún máa bá mi pa ọpọlọpọ adìẹ. Ní ọjọ́ kẹwaa kẹwaa ni wọ́n máa ń tọ́jú ọpọlọpọ waini sinu awọ fún mi. Sibẹsibẹ, n kò bèèrè owó oúnjẹ tí ó jẹ́ ẹ̀tọ́ gomina, nítorí pé ara tí ń ni àwọn eniyan pupọ jù.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Njẹ ẹran ti a pese fun mi jẹ malũ kan ati ãyo agutan mẹfa; fun ijọ kan ni a pese adiẹ fun mi pẹlu, ati lẹ̃kan ni ijọ mẹwa onirũru ọti-waini: ṣugbọn fun gbogbo eyi emi kò bere onjẹ bãlẹ, nitori iṣẹ na wiwo lori awọn enia yi.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ní ọjọ́ kọ̀ọ̀kan ni a máa rí pèṣè màlúù kan, ààyò àgùntàn mẹ́fà àti adìyẹ fún mi àti lẹ́ẹ̀kan ní ọjọ́ mẹ́wàá ni wọ́n máa ń pèṣè onírúurú wáìnì tí ó pọ̀ fún mi. Fún gbogbo èyí, èmi kò béèrè oúnjẹ baálẹ̀, nítorí ohun ti a ń béèrè lọ́wọ́ àwọn ènìyàn wọ̀nyí pọ̀ jọjọ.