Nehemiah 5:7 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Mo rò ó lọ́kàn mi, mo sì dá àwọn ọlọ́lá ati àwọn ìjòyè lẹ́bi. Mo sọ fún wọn pé, “Ẹ̀ ń ni àwọn arakunrin yín lára.” Mo bá pe ìpàdé ńlá lé wọn lórí, mo sọ fún wọn pé,
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Mo si ronu ọ̀ran na, mo si ba awọn ijoye ati awọn olori wi, mo si wi fun wọn pe, Ẹnyin ngba ẹdá olukuluku lọwọ arakunrin rẹ̀. Mo si pe apejọ nla tì wọn.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Mo rò wọ́n wò ní ọkàn mi mo sì fi ẹ̀ṣùn kan ọlọ́lá àti àwọn ìjòyè. Mo sọ fún wọn pé, ẹ̀yin ń gba owó èlé lọ́wọ́ àwọn ará ìlúu yín! Nítorí náà mo pe àpèjọ ńlá láti bá wọn wí.