Nehemiah 5:8 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
“Ní tiwa, a ti gbìyànjú níwọ̀n bí agbára wa ti mọ, a ti ra àwọn arakunrin wa tí wọ́n tà lẹ́rú fún àwọn orílẹ̀-èdè mìíràn pada, ṣugbọn ẹ̀yin tún ń ta àwọn arakunrin yín, kí wọ́n baà lè tún tà wọ́n fún wa!” Wọ́n dákẹ́, wọn kò sì lè fọhùn.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Mo si wi fun wọn pe, Awa nipa agbara wa ti rà awọn ara Juda arakunrin wa padà, ti a tà fun awọn keferi; ẹnyin o ha si mu ki a tà awọn arakunrin nyin? tabi ki a ha tà wọn fun wa? Nwọn si dakẹ, nwọn kò ri nkankan dahùn.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Mo sì wí fún wọn pé: “Níbi tí àwa ní agbára mọ, àwa ti ra àwọn Júù arákùnrin wa tí a ti tà fún àwọn tí kì í ṣe Júù padà. Nísinsìn yìí ẹ̀yìn ń ta àwọn arákùnrin yín, tí àwa sì tún ní láti rà wọ́n padà!” Wọ́n dákẹ́, nítorí wọn kò rí ohun kóhun sọ.