Nehemiah 6:1 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Nígbà tí wọ́n sọ fún Sanbalati ati Tobaya ati Geṣemu ará Arabia ati àwọn ọ̀tá wa yòókù pé a ti tún odi náà mọ, ati pé kò sí àlàfo kankan mọ́ (lóòótọ́ n kò tíì ṣe ìlẹ̀kùn sí àwọn ẹnubodè).
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
O SI ṣe, nigbati Sanballati, ati Tobiah, ati Geṣemu, ara Arabia, ati awọn ọta wa iyokù, gbọ́ pe, mo ti mọ odi na, ati pe, kò kù ibi yiya kan ninu rẹ̀, (bi emi kò tilẹ iti gbe ilẹkùn wọnni ro ni ibode li akoko na;)
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nígbà tí Sáńbálátì, Tòbáyà Géṣémù ará Árábíà àti àwọn ọ̀taa wa tó kù gbọ́ pé, mo ti tún odi náà mọ, kò sì sí àlàfo kankan tí ó ṣẹ́ kù nínú un rẹ̀—bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé èmi kò ì tí ì rì àwọn ìlẹ̀kùn ibodè ní àkókò náà.