Nehemiah 6:10 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Ní ọjọ́ kan tí mo lọ sí ilé Ṣemaaya, ọmọ Delaaya, ọmọ Mehetabeli, tí wọ́n tì mọ́lé, ó ní “Jẹ́ kí á jọ pàdé ní ilé Ọlọrun ninu tẹmpili, nítorí wọ́n ń bọ̀ wá pa ọ́, alẹ́ ni wọ́n ó sì wá.”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Mo si wá si ile Ṣemaiah ọmọ Delaiah ọmọ Mehetabeeli, ti a há mọ, o si wipe, Jẹ ki a pejọ ni ile Ọlọrun ni inu tempili ki a si tì ilẹkùn tempili; nitori nwọn o wá lati pa ọ; nitõtọ, li oru ni nwọn o wá lati pa ọ.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ní ọjọ́ kan mo lọ sí ilé Ṣemáyà ọmọ Deláyà, ọmọ Mehetabélì, ẹni tí a há mọ́ sínú ilé rẹ̀. Ó wí pé, “Jẹ́ kí a pàdé ní ilé Ọlọ́run nínú un tẹ́ḿpìlì, kí o sì jẹ́ kí a pa àwọn ìlẹ̀kùn tẹ́ḿpìlì dé, nítorí àwọn ènìyàn ń bọ̀ láti pa ọ́, ní òru ni wọn yóò wá láti pa ọ́.”