Nehemiah 6:14 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Áà, Ọlọrun mi, ranti ohun tí Tobaya ati Sanbalati ati Noadaya, wolii obinrin, ṣe sí mi, ati àwọn wolii yòókù tí wọ́n fẹ́ máa dẹ́rù bà mí.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ọlọrun mi, rò ti Tobiah ati Sanballati gẹgẹ bi iṣẹ wọn wọnyi, ati ti Noadiah, woli obinrin, ati awọn woli iyokù ti nwọn fẹ mu mi bẹ̀ru,
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
A! Ọlọ́run mi, rántí Tòbáyà àti Ṣáńbálátì, nítorí ohun tí wọ́n ti ṣe; kí o sì tún rántí Nóádáyà wòlíì obìnrin àti àwọn wòlíì tókù tí wọ́n ń gbérò láti dẹ́rù bà mí.