Nehemiah 6:16 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Nígbà tí àwọn ọ̀tá wa, ní gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè tí ó yí wa ká gbọ́ nípa rẹ̀, ẹ̀rù bà wọ́n, ìtìjú sì mú wọn, nítorí wọ́n mọ̀ pé nípa ìrànlọ́wọ́ Ọlọrun ni iṣẹ́ náà fi ṣeéṣe.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
O si ṣe, nigbati gbogbo awọn ọta wa gbọ́, gbogbo awọn keferi àgbegbe wa si bẹ̀ru, nwọn si rẹ̀wẹsi pupọ li oju ara wọn, nitori nwọn woye pe, lati ọwọ Ọlọrun wá li a ti ṣe iṣẹ wọnyi.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nígbà tí àwọn ọ̀ta wa gbọ́ èyí, gbogbo àwọn orílẹ̀ èdè tí ó yí wa ká bẹ̀rù jìnnìjìnnì sì mú wọn, nítorí wọ́n wòye pé iṣẹ́ yìí di ṣíṣe pẹ̀lú ìrànlọ́wọ́ Ọlọ́run wa.