Nehemiah 6:18 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Nítorí pé ọpọlọpọ àwọn ará Juda ni wọ́n ti bá a dá majẹmu, nítorí àna Ṣekanaya ọmọ Ara ni: ọmọ rẹ̀ ọkunrin, Jehohanani, ló fẹ́ ọmọbinrin Meṣulamu, ọmọ Berekaya.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nitori ọ̀pọlọpọ ni Juda ti ba a mulẹ nitori ti o jẹ ana Sekaniah ọmọ Ara; ọmọ rẹ̀ Johanani si ti fẹ ọmọ Meṣullamu, ọmọ Berekiah.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nítorí ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn Júdà ti mulẹ̀ pẹ̀lú u rẹ̀, nítorí tí ó jẹ́ àna Ṣekenáyà ọmọ Árà (Ṣáńbálátì fẹ́ ọmọ Ṣekenáyà) ọmọ rẹ̀ Jéhóhánánì sì tún fẹ́ ọmọbìnrin Méṣúlámì ọmọ Bérékíyà