Nehemiah 6:3 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Mo bá ranṣẹ pada sí wọn pé, mò ń ṣe iṣẹ́ pataki kan lọ́wọ́, kò ní jẹ́ kí n lè wá. Kò sì ní yẹ kí n dá iṣẹ́ náà dúró nítorí àtiwá rí wọn.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Mo si ran onṣẹ si wọn pe, Emi nṣe iṣẹ nla kan, emi kò le sọkalẹ wá: ẽṣe ti iṣẹ na yio fi duro nigbati mo ba fi i silẹ, ti mo ba si sọkalẹ tọ̀ nyin wá?
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Bẹ́ẹ̀ ni mo rán oníṣẹ́ padà pẹ̀lú èsì yìí pé; “Èmi ń ṣe iṣẹ́ ńlá kan, èmi kò le è sọ̀kalẹ̀ wá. Èéṣe tí iṣẹ́ náà yóò fi dúró, nígbà tí mo bá fi í sílẹ̀ tí mo sì sọ̀kalẹ̀ tọ̀ yín wá?”