Nehemiah 6:7 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
ati pé o tilẹ̀ ti yan àwọn wolii láti máa kéde nípa rẹ ní Jerusalẹmu pé, ‘Ọba kan wà ní Juda.’ Ó pẹ́ ni, ó yá ni, ọba yóo gbọ́ ìròyìn yìí. Nítorí náà, wá kí á jọ jíròrò nípa ọ̀rọ̀ náà.”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Iwọ pẹlu si ti yan awọn woli lati kede rẹ ni Jerusalemu wipe, Ọba wà ni Juda: nisisiyi ni a o si rò o fun ọba gẹgẹ bi ọ̀rọ wọnyi. Njẹ wá nisisiyi, ki a jọ gbimọ̀ pọ̀.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
àti pé ó ti yan àwọn wòlíì kí wọn lè kéde nípa rẹ̀ ní Jérúsálẹ́mù: ‘ọba kan wà ní Júdà!’ Nísinsìn yìí, ìròyìn yìí yóò padà sí ọ̀dọ̀ ọba; nítorí náà wá, jẹ́ kí a bá ara wa sọ̀rọ̀.”