Nehemiah 6:9 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Nítorí pé gbogbo wọn fẹ́ dẹ́rù bà wá, wọ́n lérò pé a óo jáwọ́ kúrò ninu iṣẹ́ náà, a kò sì ní lè parí rẹ̀ mọ́. Ṣugbọn adura mi nisinsinyii ni, “Kí Ọlọrun, túbọ̀ fún mi ní okun.”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nitori gbogbo wọn mu wa bẹ̀ru, wipe, Ọwọ wọn yio rọ ninu iṣẹ na, ki a má le ṣe e. Njẹ nisisiyi, Ọlọrun, mu ọwọ mi le.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Gbogbo wọn múra láti dẹ́rù bà wá, wọ́n ń rò ó wí pé, “Ọwọ́ wọn kò ní ran iṣẹ́ náà, àti wí pé wọn kò ní paríi rẹ̀.” Ṣùgbọ́n mo gbàdúrà pé, “Nísinsìn yìí Ọlọ́run fi agbára fún ọwọ́ mi.”