Nehemiah 7:3 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Mo sọ fún wọn pé, wọn kò gbọdọ̀ ṣí ẹnu ibodè Jerusalẹmu títí tí oòrùn yóo fi máa ta ni lára, kí wọ́n sì máa ti ibodè náà, kí wọ́n fi ọ̀pá ìdábùú sí i lẹ́yìn kí àwọn olùṣọ́ tó kúrò lẹ́nu iṣẹ́. Kí wọ́n yan àwọn olùṣọ́ láàrin àwọn ọmọ Jerusalẹmu, kí olukuluku ní ibùdó tirẹ̀, kí wọ́n sì máa ṣọ́ ibi tí ó bá kọjú sí ilé wọn.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Mo si wi fun wọn pe, Ẹ má jẹ ki ilẹkùn odi Jerusalemu ṣi titi õrùn o fi mú; bi nwọn si ti duro, jẹ ki wọn se ilẹkùn, ki nwọn si há wọn, ki nwọn si yan ẹ̀ṣọ ninu awọn ti ngbe Jerusalemu, olukuluku ninu iṣọ rẹ̀, ati olukuluku ninu ile rẹ̀.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Mo sọ fún wọn pé, “A kò gbọdọ̀ sí ìlẹ̀kùn Jérúsálẹ́mù títí oòrùn yóò fi mú. Nígbà tí àwọn aṣọ́bodè bá sì wà lẹ́nu iṣẹ́, jẹ́ kí wọn ti ìlẹ̀kùn kí wọn sì há wọn. Bákan náà, yàn nínú àwọn tí ń gbé Jérúsálẹ́mù gẹ́gẹ́ bí olùṣọ́. Àwọn mìíràn níbi tí a pín wọn sí àti àwọn mìíràn ní tòsí ilé e wọn.”