Nehemiah 7:6 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Orúkọ àwọn eniyan agbègbè náà, tí wọ́n pada ninu àwọn tí Nebukadinesari ọba Babiloni kó lọ sí ìgbèkùn, tí wọ́n pada sí Jerusalẹmu ati Juda, tí olukuluku wọn sì pada sí ìlú rẹ̀ nìwọ̀nyí.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Wọnyi ni awọn ọmọ igberiko, ti o gòke wá lati ìgbekun ninu awọn ti a ti ko lọ, ti Nebukadnesari ọba Babiloni ti ko lọ, ti nwọn tun padà wá si Jerusalemu, ati si Juda, olukuluku si ilu rẹ̀.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Èyí ni àwọn ènìyàn agbègbè náà tí wọ́n sọ̀kalẹ̀ wá láti ìgbèkùn, àwọn tí Nebukadinéṣárì ọba Bábílónì ti kó ní ìgbékùn (wọ́n padà sí Jérúsálẹ́mù àti Júdà, olúkúlùkù sí ìlúu rẹ̀.