Nehemiah 7:61 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Àwọn tí wọ́n wá láti Teli Mela, ati láti Teli Hariṣa, Kerubu, Adoni, ati Imeri, ṣugbọn tí wọn kò mọ ilé baba wọn tabi ibi tí wọ́n ti ṣẹ̀, tí kò sì sí ẹ̀rí tí ó dájú, bóyá ọmọ Israẹli ni wọ́n tabi wọn kì í ṣe ọmọ Israẹli nìwọ̀nyí:
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Awọn wọnyi li o si goke lati Telhariṣa, Kerubu, Addoni, ati Immeri wá: ṣugbọn nwọn kò le fi ile baba wọn hàn, tabi iran wọn, bi nwọn iṣe ti Israeli.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Àwọn wọ̀nyí gòkè wá láti Tẹ́lì-mẹ́là, Tẹ́lì-Hásíhà, Kérúbù, Ádónì àti Ímérì, ṣùgbọ́n wọn kò lè sọ pẹ̀lú ìdánilójú pé ìdílé àwọn wá láti ara ìran ẹ̀yà Ísírẹ́lì: