Nehemiah 7:63 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Bákan náà ni àwọn ọmọ alufaa wọnyi: àwọn ọmọ Hobaaya, àwọn ọmọ Hakosi, ati àwọn ọmọ Basilai (tí wọ́n fẹ́ iyawo lára àwọn ọmọ Basilai ará Gileadi, ṣugbọn tí wọn tún ń jẹ́ orúkọ àwọn àna wọn.)
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ati ninu awọn alufa: awọn ọmọ Habaiah, awọn ọmọ Kosi, awọn ọmọ Barsillai, ti o ni ọkan ninu awọn ọmọbinrin Barsillai, ara Gileadi, li aya, a si npè e nipa orukọ wọn.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Lára àwọn àlùfáà ni: — àwọn ìran — Hóbáíyà, Hákósì àti Básíláì (ọkùnrin tí ó fẹ́ ọmọbìnrin Básíláì ará Gílíádì, ẹni tí a ń fi orúkọ yìí pè).