Nehemiah 7:70 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Àwọn olórí ní ìdílé kọ̀ọ̀kan kópa ninu iṣẹ́ náà. Gomina fi ẹgbẹrun (1,000) ìwọ̀n diramu wúrà sí ilé ìṣúra ati aadọta àwo kòtò, ati ẹẹdẹgbẹta ó lé ọgbọ̀n (530) ẹ̀wù alufaa sí i.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Omiran ninu awọn olori ninu awọn baba fi nkan si iṣẹ na. Bãlẹ fi ẹgbẹrun dramu wura, ãdọta awokoto, ọrindilẹgbẹta le mẹwa ẹwu alufa sinu iṣura na.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Díẹ̀ lára àwọn olóórí ìdílé náà kópa nínú un ṣíṣe iṣẹ́ náà Baálẹ̀ fún ilé ìṣúra ní ẹgbẹ̀rún dírámásì wúrà, (kílò mẹ́jọ ààbọ̀) àádọ́ta bóòlù àti ọ̀rìndínlẹ́gbẹ̀ta lé mẹ́wàá ẹ̀wù fún àwọn àlùfáà.