Nehemiah 7:73 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Bẹ́ẹ̀ ni àwọn alufaa ṣe bẹ̀rẹ̀ sí gbé àwọn ìlú Juda, pẹlu àwọn ọmọ Lefi, ati àwọn aṣọ́bodè, ati àwọn akọrin, ati díẹ̀ lára àwọn eniyan náà, pẹlu àwọn iranṣẹ tẹmpili, ati gbogbo àwọn ọmọ Israẹli, kaluku ń gbé ìlú rẹ̀. Nígbà tí yóo fi di oṣù keje, àwọn ọmọ Israẹli ti wà ní àwọn ìlú wọn.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Bẹ̃ni awọn alufa, ati awọn ọmọ Lefi, ati awọn oludena, ati awọn akọrin, ati ninu awọn enia, ati awọn Netinimu, ati gbogbo Israeli, ngbe ilu wọn; nigbati oṣu keje si pé, awọn ọmọ Israeli wà ni ilu wọn.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Àwọn àlùfáà, àwọn Léfì, àwọn aṣọ́bodè, àwọn akọrin, àwọn ènìyàn díẹ̀, àwọn ìránṣẹ́ ilé Ọlọ́run, àti gbogbo ènìyàn Ísírẹ́lì wà ní ìlúu wọn. Nígbà tí ó di oṣù keje tí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì sì ti wà nínú ìlúu wọn,