Nehemiah 8:1 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Ní ọjọ́ kinni oṣù náà, gbogbo wọn pátá péjọ pọ̀ sí gbangba ìta níwájú Ẹnubodè Omi, wọ́n sì sọ fún Ẹsira, akọ̀wé, pé kí ó mú ìwé òfin Mose tí OLUWA fún àwọn ọmọ Israẹli wá.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
NIGBANA ni gbogbo awọn enia ko ara wọn jọ bi enia kan si ita ti o wà niwaju ẹnu-bode omi; nwọn si sọ fun Esra akọwe lati mu iwe ofin Mose wá, ti Oluwa ti paṣẹ fun Israeli.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
gbogbo àwọn ènìyàn kó ara wọn jọ bí ẹnìkan ní gbangba ìta níwájú Ibodè-Omi. Wọ́n sọ fún Ẹ́sírà akọ̀wé pé kí ó gbé ìwé òfin Mósè jáde, èyí tí OLÚWA ti pa láṣẹ fún Ísírẹ́lì.