Nehemiah 8:10 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Nehemaya bá sọ fún wọn pé, “Ẹ máa lọ, ẹ jẹ ẹran ọlọ́ràá, ẹ mu waini dídùn, kí ẹ sì fi oúnjẹ ranṣẹ sí àwọn tí wọn kò bá ní, nítorí pé ọjọ́ mímọ́ ni ọjọ́ òní jẹ́ fún OLUWA wa, ẹ má sì banújẹ́, nítorí pé ayọ̀ OLUWA ni agbára yín.”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nigbana ni o wi fun wọn pe, Ẹ lọ, ẹ jẹ ọ̀ra ki ẹ si mu ohun didùn, ki ẹ si fi apakan ipin ranṣẹ si awọn ti a kò pèse fun: nitori mimọ́ ni ọjọ yi fun Oluwa: ẹ máṣe banujẹ; nitori ayọ̀ Oluwa on li agbàra nyin.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nehemáyà wí pé, “Ẹ lọ kí ẹ gbádùn oúnjẹ tí ẹ yàn láàyò kí ẹ sì mú ohun dídùn, kí ẹ sì mú díẹ̀ ránṣẹ́ sí àwọn tí kò ní. Ọjọ́ yìí, mímọ́ ni fún OLÚWA wa. Ẹ má ṣe banújẹ́, nítorí ayọ̀ OLÚWA ni agbára yín.”