Nehemiah 8:15 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
ati pé kí wọ́n kéde rẹ̀ ní gbogbo àwọn ìlú wọn ati ni Jerusalẹmu pé, “Ẹ lọ sí orí àwọn òkè, kí ẹ sì mú àwọn ẹ̀ka igi olifi wá, ati ti paini, ati ti mitili, ati imọ̀ ọ̀pẹ, ati ẹ̀ka àwọn igi mìíràn láti fi pàgọ́, gẹ́gẹ́ bí ó ti wà ní àkọsílẹ̀.”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Pe, ki nwọn funrere, ki nwọn kede ni gbogbo ilu wọn, ati ni Jerusalemu, wipe, Ẹ jade lọ si òke, ki ẹ si mu ẹka igi olifi, ẹka igi pine, ati ẹka igi matili (myrtle) imọ ọpẹ, ati ẹka igi ti o tobi, lati ṣe agọ gẹgẹ bi a ti kọ ọ.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
àti kí wọn kéde ọ̀rọ̀ yìí, kí wọn sì tàn-án kálẹ̀ ní gbogbo ìlúu wọn àti ní Jérúsálẹ́mù: “Ẹ jáde lọ sí ìlú olókè, kí ẹ mú àwọn ẹ̀ka inú olífì àti ẹ̀ka igi olífì ìgbẹ́, àti láti inú máítílì, àwọn imọ̀ ọ̀pẹ àti àwọn igi tí ó léwé dáradára wá, láti ṣe àgọ́”—gẹ́gẹ́ bí a ti kọ ọ́.