Nehemiah 8:16 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Àwọn eniyan náà jáde, wọ́n sì lọ wá imọ̀ ọ̀pẹ ati ẹ̀ka igi wá, wọ́n sì pàgọ́ fún ara wọn, kaluku pàgọ́ sí orí ilé, ati sí àgbàlá ilé wọn ati sí àgbàlá ilé Ọlọrun pẹlu, wọ́n pàgọ́ sí ìta Ẹnubodè Omi ati sí ìta Ẹnubodè Efuraimu.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Bẹ̃ni awọn enia na jade lọ, nwọn si mu wọn wá, nwọn pa agọ fun ara wọn, olukuluku lori orule ile rẹ̀, ati li àgbala wọn, ati li àgbala ile Ọlọrun, ati ni ita ẹnu-bode omi, ati ni ita ẹnu-bode Efraimu.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Bẹ́ẹ̀ ni àwọn ènìyàn jáde lọ, wọ́n sì mú àwọn ẹ̀ka wá, wọ́n sì kọ́ àgọ́ fún ara wọn sí orí òrùlé ara wọn, ní àgbàlá wọn àti ní àgbàlá ilé Ọlọ́run àti ní ìta gbangba lẹ́gbẹ̀ẹ́ ẹnu ibodè omi àti èyí tí ó wà lẹ́gbẹ̀ẹ́ ẹnu ibodè Éúfúrémù.