Nehemiah 8:17 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Gbogbo àpéjọ àwọn tí wọ́n pada dé láti oko ẹrú pa àgọ́, wọ́n sì ń gbé inú àgọ́ wọn. Láti ìgbà ayé Joṣua ọmọ Nuni, títí di àkókò náà, àwọn ọmọ Israẹli kò pàgọ́ bẹ́ẹ̀ rí, gbogbo wọn sì yọ ayọ̀ ńlá.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Gbogbo ijọ enia ninu awọn ti o pada bọ̀ lati oko-ẹrú si pa agọ, nwọn si gbe abẹ awọn agọ na: nitori lati akokò Joṣua ọmọ Nuni wá, titi di ọjọ na awọn ọmọ Israeli kò ṣe bẹ̃. Ayọ̀ nlanla si wà.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Gbogbo ìjọ ènìyàn tí wọ́n padà láti ìgbèkùn kọ́ àgọ́, wọ́n sì ń gbé inú un wọn. Láti ọjọ́ Jóṣúà ọmọ Núnì títí di ọjọ́ náà, àwọn ọmọ Ísírẹ́lì kò tí ì ṣe àjọyọ̀ ọ rẹ̀ bí irú èyí. Ayọ̀ ọ wọn sì pọ̀.