Nehemiah 8:18 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Lojoojumọ, láti ọjọ́ kinni títí di ọjọ́ tí àsè náà parí, ni wọ́n ń kà ninu ìwé òfin. Wọ́n ṣe àjọ̀dún àsè náà fún ọjọ́ meje, ní ọjọ́ kẹjọ, wọ́n pe àpéjọ tí ó lọ́wọ̀, gẹ́gẹ́ bí ìlànà tí ó wà ninu àkọsílẹ̀.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Esra si kà ninu iwe ofin Ọlọrun li ojojumọ, lati ọjọ kini titi de ọjọ ikẹhin. Nwọn si pa àse na mọ li ọjọ meje, ati lọjọ kẹjọ, nwọn ni apejọ ti o ni ìronu gẹgẹ bi iṣe wọn.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ẹ́sírà kà nínú ìwé òfin Ọlọ́run, bí ọjọ́ ṣe ń gorí ọjọ́, láti ọjọ́ kìn-ín-ní dé ọjọ́ ìkẹyìn. Wọ́n ṣe àjọyọ̀ àjọ náà fún ọjọ́ méje, ní ọjọ́ kẹjọ wọ́n ní àpèjọ, ní ìbámu pẹ̀lú òfin.