Nehemiah 8:2 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Ẹsira, alufaa, gbé ìwé òfin náà jáde siwaju àpéjọ náà, tọkunrin tobinrin, gbogbo àwọn tí wọ́n lè gbọ́ kíkà òfin náà kí ó sì yé wọn ni wọ́n péjọ, ní ọjọ́ kinni oṣù keje.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Esra alufa si mu ofin na wá iwaju ijọ t'ọkunrin t'obinrin, ati gbogbo awọn ti o le fi oye gbọ́, li ọjọ kini oṣu ekeje.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ní ọjọ́ kìn-ín-ní oṣù keje ni àlùfáà Ẹ́sírà gbé ìwé òfin jáde ní iwájú ìjọ ènìyàn, èyí tí ó jẹ́ àpapọ̀ ọkùnrin àti obìnrin àti gbogbo àwọn ènìyàn tí wọ́n le è gbọ́ ọ ní àgbọ́yé.