Nehemiah 8:3 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Ẹsira ka ìwé òfin náà sí etígbọ̀ọ́ wọn. Ó kọjú sí ìta gbangba tí ó wà lẹ́bàá Ẹnubode Omi láti àárọ̀ kutukutu títí di ọ̀sán, níwájú tọkunrin tobinrin ati àwọn tí ọ̀rọ̀ òfin náà yé, gbogbo wọn ni wọ́n sì tẹ́tí sí ìwé òfin náà.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
O si kà ninu rẹ̀ niwaju ita ti o wà niwaju ẹnu-bode omi lati owurọ titi di idaji ọjọ, niwaju awọn ọkunrin ati awọn obinrin, ati awọn ti o le ye; gbogbo enia si tẹtisilẹ si iwe ofin.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ó kà á sókè láti òwúrọ̀ títí di ọ̀sán (bí agogo méjìlá) bí ó ti kọjú sí ìta ní iwájú Ibodè-Omi ní ojú u gbogbo ọkùnrin, obìnrin àti àwọn ènìyàn tó kù tí òye le è yé tí wọ́n wà níbẹ̀. Gbogbo ènìyàn sì fetísílẹ̀ sí ìwé òfin náà pẹ̀lú ìfarabalẹ̀.