Nehemiah 8:9 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Nehemaya tí ó jẹ́ gomina, ati Ẹsira, alufaa ati akọ̀wé, ati àwọn ọmọ Lefi tí wọ́n kọ́ àwọn eniyan náà sọ fún gbogbo wọn pé, “Ọjọ́ mímọ́ ni ọjọ́ òní jẹ́ fún OLUWA Ọlọrun yín. Ẹ má banújẹ́ tabi kí ẹ sọkún.” Nítorí pé gbogbo wọn ni wọ́n ń sọkún nígbà tí wọn ń gbọ́ ọ̀rọ̀ inú òfin náà.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ati Nehemiah ti iṣe bãlẹ, ati Esra alufa, akọwe, ati awọn ọmọ Lefi, ti o kọ́ awọn enia wi fun gbogbo enia pe, Ọjọ yi jẹ mimọ́ fun Oluwa Ọlọrun nyin; ẹ má ṣọ̀fọ ki ẹ má si sọkún. Nitori gbogbo awọn enia sọkún, nigbati nwọn gbọ́ ọ̀rọ ofin.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nígbà náà ni Nehemáyà tí ó jẹ́ baálẹ̀, Ẹ́sírà àlùfáà àti akọ̀wé, àti àwọn Léfì tí wọ́n ń kọ́ àwọn ènìyàn wí fún gbogbo wọn pé, “Ọjọ́ yìí jẹ́ ọjọ́ mímọ́ fún OLÚWA Ọlọ́run yín. Ẹ má ṣe ṣọ̀fọ̀ tàbí sumkún” Nítorí gbogbo àwọn ènìyàn ti ń sunkún bí wọ́n ti ń tẹ́tí sí ọ̀rọ̀ inú òfin náà.