Nehemiah 9:15 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
O fún wọn ní oúnjẹ láti ọ̀run wá nígbà tí ebi ń pa wọ́n, o sì ń fún wọn ní omi mu láti inú àpáta nígbà tí òùngbẹ ń gbẹ wọ́n. O ní kí wọ́n lọ gba ilẹ̀ tí o ti ṣèlérí láti fún wọn bí ohun ìní wọn.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
O si fun wọn li onjẹ lati ọrun wá fun ebi wọn, o si mu omi lati inu apata wá fun orungbẹ wọn, o si ṣe ileri fun wọn pe, ki nwọn lọ ijogun ilẹ na ti iwọ ti bura lati fi fun wọn.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ìwọ fún wọn ní oúnjẹ láti ọ̀run wá nígbà tí ebi ń pa wọ́n àti nígbà òrùngbẹ o fún wọn ní omi láti inú àpáta; ó sì sọ fún wọn pé, kí wọ́n lọ láti lọ gba ilẹ̀ náà tí ìwọ ti jẹ́ ẹ̀jẹ́ láti fi fún wọn.