Nehemiah 9:24 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Àwọn ọmọ wọn lọ sí ilẹ̀ náà, wọ́n sì gbà á, o ṣẹgun àwọn ará Kenaani tí wọn ń gbé orí ilẹ̀ náà tẹ́lẹ̀, o sì fi wọ́n lé àwọn ọmọ Israẹli lọ́wọ́, àtàwọn, àtọba wọn, àtilẹ̀ wọn, kí àwọn ọmọ Israẹli lè ṣe wọ́n bí wọ́n bá ti fẹ́.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Bẹ̃li awọn ọmọ na wọ inu rẹ̀ lọ, nwọn si gbà ilẹ na, iwọ si tẹ ori awọn ara ilẹ na ba niwaju wọn, awọn ara Kenaani, o si fi wọn le ọwọ wọn, pẹlu ọba wọn, ati awọn enia ilẹ na, ki nwọn ki o le fi wọn ṣe bi o ti wù wọn.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Àwọn ọmọ wọn wọ inú un rẹ̀, wọ́n sì gbà ilẹ̀ náà. Ìwọ sì tẹ orí àwọn aráa Kénánì, tí ń gbé inú ilẹ̀ náà ba níwájúu wọn; ó fi àwọn aráa Kénánì lé wọn lọ́wọ́ pẹ̀lú àwọn ọba wọn àti àwọn ènìyàn ilẹ̀ náà kí wọn ṣe wọn bí ó ti wù wọ́n.