Nehemiah 9:25 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Àwọn ọmọ Israẹli gba gbogbo àwọn ìlú olódi ati ilẹ̀ tí ó lẹ́tù lójú, wọ́n sì gba ilé tí ó kún fún ọpọlọpọ àwọn nǹkan dáradára, ati kànga, ọgbà àjàrà, igi olifi ati ọpọlọpọ igi eléso, nítorí náà wọ́n jẹ wọ́n yó, wọ́n sanra, wọ́n sì ń gbádùn ara wọn ninu oore ńlá rẹ.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nwọn si gbà ilu alagbara, ati ilẹ ọlọra, nwọn si gbà ilẹ ti o kún fun ohun rere, kanga, ọgba-ajara, ọgba-olifi, ati igi eleso, li ọ̀pọlọpọ: bẹ̃ni nwọ́n jẹ, nwọn si yo, nwọ́n sanra, nwọn si ni inu-didùn ninu ore rẹ nla.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Wọ́n gba àwọn ìlú olódì àti ilẹ̀ ọlọ́ràá; wọ́n gba àwọn ilé tí ó kún fún onírúurú gbogbo nǹkan rere, àwọn kàǹga tí a ti gbẹ́, awọn ọgbà àjàrà, awọn ọgbà ólífì àti àwọn igi eléso ní ọ̀pọ̀lọpọ̀. Wọ́n jẹ, wọ́n yó, wọ́n sì sanra dáadáa; wọ́n sì yọ̀ nínú oore ńlá rẹ