Nehemiah 9:26 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
“Ṣugbọn, wọ́n ṣe àìgbọràn, wọ́n sì ṣọ̀tẹ̀ sí ọ. Wọ́n pa àwọn òfin rẹ tì sí apákan, wọ́n pa àwọn wolii rẹ tí wọ́n ti ń kìlọ̀ fún wọn pé kí wọ́n yipada sí ọ, wọ́n sì ń hùwà àbùkù sí ọ.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ṣugbọn nwọn ṣe alaigbọràn, nwọn si ṣọ̀tẹ si ọ, nwọn si gbe ofin rẹ sọ si ẹ̀hin wọn, nwọn si pa awọn woli rẹ ti nsọ fun wọn lati yipada si ọ, nwọn si ṣe imunibinu nla.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
“Ṣùgbọ́n wọ́n ṣe àìgbọ́ràn, wọ́n sì ṣọ̀tẹ̀ sí ọ; wọ́n gbàgbé òfin rẹ. Wọ́n pa àwọn wòlíì rẹ, tí o fi gbà wọn ni ìyànjú pé kí wọn yí padà sí ọ; wọ́n sì ṣe ọ̀rọ̀-òdì tí ó burú jàì.