Nehemiah 9:29 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Ò sì máa kìlọ̀ fún wọn kí wọ́n lè yipada sí òfin rẹ. Sibẹ wọn a máa hùwà ìgbéraga, wọn kìí sìí pa òfin rẹ mọ́, kàkà bẹ́ẹ̀ wọn a máa ṣẹ̀ sí òfin rẹ, tí ó jẹ́ pé bí eniyan bá pamọ́, ẹni náà yóo yè. Ṣugbọn wọn ń dágunlá, wọ́n ń ṣe orí kunkun, wọn kò sì gbọ́ràn.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Iwọ si jẹri gbè wọn ki iwọ ki o le tun mu wọn wá sinu ofin rẹ, ṣugbọn nwọn hu ìwa igberaga, nwọn kò si fi eti si ofin rẹ, nwọn si ṣẹ̀ si idajọ rẹ (eyiti bi enia ba ṣe on o yè ninu wọn), nwọn si gún èjika, nwọn mu ọrùn wọn le, nwọn kò si fẹ igbọ́.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
“Ìwọ kìlọ̀ fún wọn làti Padà sínú òfin rẹ, ṣùgbọ́n wọ́n hu ìwà ìgbéraga, wọ́n sì ṣe àìgbọ́ràn si àṣẹ rẹ. Wọ́n sẹ̀ sí ìlànà rẹ, nípa èyí tí ènìyàn yóò yè tí wọ́n bá pa wọ́n mọ́. Nínú agídí ọkàn wọ́n kọ ẹ̀yìn sí ọ, wọ́n jẹ́ olóríkunkun wọn kò sì fẹ́ gbọ́.