Nehemiah 9:3 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Wọ́n dúró ní ààyè wọn, wọ́n sì ka ìwé òfin OLUWA Ọlọrun wọn fún bíi wakati mẹta lọ́jọ́ náà. Lẹ́yìn náà, wọ́n jẹ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ wọn fún nǹkan bíi wakati mẹta, wọ́n sì sin OLUWA Ọlọrun wọn.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nwọn si dide duro ni ipò wọn, nwọn si fi idamẹrin ọjọ kà ninu iwe ofin Oluwa Ọlọrun wọn; nwọn si fi idamẹrin jẹwọ, nwọn si sìn Oluwa Ọlọrun wọn.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Wọ́n dúró sí ibi tí wọ́n wà, wọ́n sì fi ìdámẹ́rin ọjọ́ kà nínú ìwé òfin OLÚWA Ọlọ́run wọn, wọ́n sì tún fi ìdámẹ́rin mìíràn ní ìjẹ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ àti ní ṣíṣin OLÚWA Ọlọ́run wọn.