Nehemiah 9:30 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Ọpọlọpọ ọdún ni o fi mú sùúrù pẹlu wọ́n, tí o sì ń kìlọ̀ fún wọn nípasẹ̀ Ẹ̀mí rẹ, láti ẹnu àwọn wolii rẹ, sibẹ wọn kò fetí sílẹ̀. Nítorí náà ni o ṣe jẹ́ kí àwọn tí ń gbé ilẹ̀ náà ṣẹgun wọn.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Sibẹ ọ̀pọlọpọ ọdun ni iwọ fi mu suru fun wọn ti o si fi ẹmi rẹ jẹri gbè wọn ninu awọn woli rẹ: sibẹ̀ nwọn kò fi eti silẹ: nitorina ni iwọ ṣe fi wọn le ọwọ awọn enia ilẹ wọnni.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Fún ọ̀pọ̀lọ̀pọ̀ ọdún ni ìwọ fi ní ṣùúrù pẹ̀lùu wọn. Nìpa ẹ̀míì rẹ ni ìwọ kìlọ̀ fún wọn nípaṣẹ̀ àwọn wòlíì. Síbẹ̀ wọn kò fi etí sílẹ̀, nìtorì náà ni ìwọ ṣe fi wọ́n lé àwọn aládùúgbò wọn lọ́wọ́.