Nehemiah 9:31 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Ṣugbọn nítorí àánú rẹ ńlá, o kò jẹ́ kí wọ́n parun patapata, bẹ́ẹ̀ ni o kò pa wọ́n tì, nítorí pé Ọlọrun olóore ọ̀fẹ́ ati aláàánú ni ọ́.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ṣugbọn nitori ãnu rẹ nla iwọ kò run wọn patapata, bẹ̃ni iwọ kò kọ̀ wọn silẹ; nitori iwọ li Ọlọrun olore-ọfẹ ati alãnu.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ṣùgbọ́n nínú ọ̀pọ̀ àánú rẹ, ìwọ kò mú òpin bá wọn tàbí kọ̀ wọ́n sílẹ̀, nítorí ìwọ ni Ọlọ́run olóore ọ̀fẹ́ àti aláàánú.