Nehemiah 9:32 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
“Nítorí náà, nisinsinyii Ọlọrun wa, Ọlọrun tí ó tóbi, tí ó sì lágbára, Ọlọrun tí ó bani lẹ́rù, Ọlọrun tí máa ń mú ìlérí ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀ ṣẹ, má fi ojú kékeré wo gbogbo ìnira tí ó dé bá wa yìí, ati èyí tí ó dé bá àwọn ọba wa, ati àwọn olórí wa, àwọn alufaa wa, ati àwọn wolii wa, àwọn baba wa, ati gbogbo àwọn eniyan rẹ, láti ìgbà àwọn ọba Asiria títí di ìsinsìnyìí.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Njẹ nitorina, Ọlọrun wa, Ọlọrun ti o tobi, ti o li agbara, ti o si li ẹ̀ru, ẹniti npa majẹmu ati ãnu mọ, má jẹ ki gbogbo iyọnu na dabi ohun kekere niwaju rẹ, o de bá wa, awọn ọba wa, awọn ijoye wa, ati awọn alufa wa, ati awọn woli wa, ati awọn baba wa, ati gbogbo awọn enia rẹ lati akoko ọba Assiria wá, titi o fi di oni yi.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
“Ǹjẹ́ nítorí náà, Ọlọ́run wa, Ọlọ́run tí ó tóbi, tí ó lágbára, tí ó sì ní ẹ̀rù, ẹni tí ó pa májẹ̀mú ìfẹ́ mọ́, má ṣe jẹ́ gbogbo ìnira yìí dàbí ohun kékeré ní ojúù rẹ—ìnira tí ó ti wá sóríi wa, sórí àwọn ọba wa àti àwọn olórí wa, sórí àwọn àlùfáà wa àti àwọn wòlíì, sórí àwọn baba wa àti sórí gbogbo ènìyàn rẹ̀, láti àwọn ọjọ́ àwọn ọba Áṣíríà wá títí di òní.