Nehemiah 9:5 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Lẹ́yìn náà ni àwọn ọmọ Lefi wọnyi: Jeṣua, Kadimieli, Bani, Haṣabineya, Ṣerebaya, Hodaya, Ṣebanaya ati Petahaya, pè wọ́n pé, “Ẹ dìde dúró kí ẹ sì yin OLUWA Ọlọrun yín lae ati laelae. Ìyìn ni fún orúkọ rẹ̀ tí ó lógo, tí ó ga ju gbogbo ibukun ati ìyìn lọ.”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Awọn ọmọ Lefi, Jeṣua, Kadmieli, Bani, Haṣabaiah, Ṣerebiah, Hodijah, Sebaniah, ati Pelaniah, si wipe: Ẹ dide, ki ẹ fi iyìn fun Oluwa Ọlọrun nyin lai ati lailai: ibukun si ni fun orukọ rẹ ti o li ogo, ti o ga jù gbogbo ibukun ati iyìn lọ.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nígbà náà ni àwọn ọmọ Léfì: Jéṣúà, Bánì, Háṣábínéáyà, Ṣérébáyà, Hódáyà, Ṣébánáyà àti Pétaíáyà—wí pé: “Ẹ dìde ẹ fi ìyìn fún OLÚWA Ọlọ́run yín, tí ó wà láé àti láéláé.” “Ìbùkún ni fún orúkọ ọ̀ rẹ tí ó ní ògo, kí ó sì di gbígbéga ju gbogbo ìbùkún àti ìyìn lọ.