Numbers 1:51 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
OLUWA ní, “Nígbà tí ẹ bá fẹ́ ṣí lọ siwaju, kí àwọn ọmọ Lefi tú Àgọ́ Ẹ̀rí palẹ̀ kí wọ́n rù ú. Nígbà tí ẹ bá sì dúró, àwọn ọmọ Lefi ni kí wọn pa Àgọ́ náà. Bí ẹnikẹ́ni tí kì í ṣe ọmọ Lefi bá súnmọ́ tòsí wọn, pípa ni kí wọ́n pa á.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nigbati agọ́ na ba si ṣí siwaju, ki awọn ọmọ Lefi ki o tú u palẹ: nigbati nwọn o ba si pa agọ́ na, awọn ọmọ Lefi ni ki o gbé e duro: alejó ti o ba sunmọtosi, pipa ni.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ìgbàkígbà tí àgọ́ yóò bá tẹ̀ṣíwájú, àwọn ọmọ Léfì ni yóò tu palẹ̀, nígbàkígbà tí a bá sì tún pa àgọ́, àwọn ọmọ Léfì náà ni yóò ṣe é. Ẹnikẹ́ni tó bá súnmọ́ tòsí ibẹ̀, pípa ni kí ẹ pa á