Numbers 10:21 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Lẹ́yìn wọn ni àwọn ọmọ Kohati tí wọ́n ru àwọn ohun èlò mímọ́ tó ṣí. Èyí jẹ́ kí àwọn ọmọ Geriṣoni ati àwọn ọmọ Merari rí ààyè láti pa Àgọ́ Àjọ náà kí àwọn ọmọ Kohati tó dé.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Awọn ọmọ Kohati ti nrù ohun mimọ́ si ṣí: awọn ti iṣaju a si ma gbé agọ́ ró dè atidé wọn.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nígbà náà ni àwọn ọmọ Kóhátì tí ń ru ohun mímọ́ náà gbéra. Àwọn ti àkọ́kọ́ yóò sì ti gbé tabánákù dúró kí wọn tó dé.