Numbers 10:22 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Lẹ́yìn náà ni àwọn tí wọ́n wà lábẹ́ ọ̀págun ẹ̀yà Efuraimu ṣí, wọ́n tò ní ìsọ̀rí-ìsọ̀rí. Eliṣama ọmọ Amihudu ni olórí wọn.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ọpágun ibudó awọn ọmọ Efraimu si ṣí gẹgẹ bi ogun wọn: Eliṣama ọmọ Ammihudu si li olori ogun rẹ̀.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Àwọn ìpín tó wà ní ibùdó Éfúráímù ló tún kàn lábẹ́ ọ̀págun wọn. Elisámà ọmọ Ámíhúdì ni ọ̀gágun wọn.