Numbers 10:29 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Mose sọ fún Hobabu ọmọ Reueli, baba iyawo rẹ̀, ará Midiani, pé: “Àwa ń lọ sí ilẹ̀ tí OLUWA ti ṣe ìlérí láti fún wa, máa bá wa kálọ, a óo sì ṣe ọ́ dáradára, nítorí OLUWA ti ṣe ìlérí ibukun fún Israẹli.”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Mose si wi fun Hobabu, ọmọ Ragueli ara Midiani, ana Mose pe, Awa nṣí lọ si ibi ti OLUWA ti wi pe, Emi o fi i fun nyin: wá ba wa lọ, awa o ṣe ọ li ore: nitoripe OLUWA sọ̀rọ rere nipa Israeli.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Mósè sì sọ fún Hóbábì ọmọ Réúélì ará Mídíánì tí í se àna Mósè pé, “A ń gbéra láti lọ sí ibi tí OLÚWA sọ pé, ‘Èmi ó fi fún un yín.’ Bá wa lọ àwa ó se ọ́ dáradára nítorí pé OLÚWA ti ṣèlérí ohun rere fún Ísírẹ́lì.”