Numbers 10:6 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Bí ẹ bá fọn fèrè ìdágìrì lẹẹkeji, àwọn tí wọ́n pàgọ́ sí ìhà gúsù yóo ṣí, wọn yóo sì tẹ̀síwájú. Ìgbàkúùgbà tí ẹ bá fẹ́ tẹ̀síwájú ni kí ẹ máa fọn fèrè ìdágìrì.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nigbati ẹnyin ba si fun ipè idagiri nigba keji, nigbana ni ki awọn ibudó ti o wà ni ìha gusù ki o ṣì siwaju: ki nwọn ki o si fun ipè idagiri ṣíṣi wọn.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nígbà tí o bá fun ìpè ìdágìrì kejì, ibùdó tó wà ní ìhà gúúsù ni yóò gbéra. Ìpè ìdágìrì yìí ni yóò jẹ́ àmì fún gbígbéra.