Numbers 10:9 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Nígbà tí ẹ bá ń lọ bá àwọn ọ̀tá yín jà lójú ogun láti gba ara yín lọ́wọ́ àwọn tí ń ni yín lára, ẹ óo fọn fèrè ìdágìrì. OLUWA Ọlọrun yín yóo sì ranti yín, yóo sì gbà yín lọ́wọ́ àwọn ọ̀tá yín.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Bi ẹnyin ba si lọ si ogun ni ilẹ nyin lọ ipade awọn ọtá ti nni nyin lara, nigbana ni ki ẹnyin ki o fi ipè fun idagiri; a o si ranti nyin niwaju OLUWA Ọlọrun nyin, a o si gbà nyin lọwọ awọn ọtá nyin.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nígbà tí ẹ bá lọ jagun pẹ̀lú àwọn ọ̀ta tó ń ni yín lára ní ilẹ̀ yín, ẹ fun ìpè ìdágìrì pẹ̀lú fèrè. A ó sì ránti yín níwájú OLÚWA, Ọlọ́run yín yóò sì gbà yín lọ́wọ́ àwọn ọ̀ta yín.